Ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹsàn-án ọdún 2022, Adarí Ẹgbẹ́ Ìdàgbàsókè Àwọn Òṣìṣẹ́ ṣe àtẹ̀jáde lérefèé nípa ohun tí ìtumọ̀ ìdarí jẹ́ nínú ìwádìí wọn sí ẹgbẹ́ alájùmọ̀ṣe wa fún àyẹ̀wò. A ṣe àgbàwọlé àwọn èsì, ìbéèrè àti àbá awọn ọmọ ẹgbẹ́ alájùmọ̀ṣe káàkiri àwọn ẹgbẹ́jẹgbẹ́ oníṣẹ́ orí pẹpẹ Wikipedia. Àwọn ìgbìmọ̀ òṣìṣẹ́ náà ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti àyẹ̀wò fínnífínní lórí èsì àbájáde náà, wọ́n ṣe àtúnkọ àti àtúnṣe lórí ìtumọ̀ náà, wọ́n sì ṣe àtẹ̀jáde àtúnṣe náà lórí pẹpẹ Meta-wiki lógúnjọ́ oṣù kẹwàá ọdún 2022. A dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ṣiṣẹ́ takuntakun lórí àbájáde yìí.
Láti ìgbà náà, a ti ṣe ìpàdé ìpè pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àgbègbè káríayé méjì láti ṣe àjọrò lórí àwọn èsì àbájáde àkókò náà. Bákan náà, a lo àǹfààní náà láti “gbọ́ kàn lẹ́nu oníkàn” lórí àwọn ìrírí àti ìtàn àwọn ìdarí tí àwọn adarí ẹgbẹ́ àgbègbè wọn káàkiri àgbáyé.
Nínú àwọn abala ìsàlẹ̀ wọ̀nyí, a máa ṣe àjọpín kókó àwọn èsì wọ̀nyí nípa mímẹ́nu bá pàtàkì àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ náà àti àwọn kùdìẹ̀kudiẹ wọn.
Àwọn èsì tí a gbà
Àwọn èsì lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan tí a mẹ́nu bá nínú àbájáde àti ìwádìí tí ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ọgbọ́n-inú, tí a mọ̀ sí oju opo Movement Strategy, a gba àwọn ìdáhùn lórí onírúurú ọ̀nà àti èdè. A ṣe àyẹ̀wò àwọn ìwádìí náà lédè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí pẹpẹ Meta-wiki, lórí àwọn ìkànnì afìwéránṣẹ́ alákòópọ̀ ní àgbègbè àti kókó-iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà lórí ẹgbẹ́ ìkànnì-ayélujára àti tààrà sí àwọn ẹgbẹ́ àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe ìpàdé – ìpè pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àgbègbè abẹ́lé àti ẹgbẹ́ àgbègbè àgbáyé méjì láti gba àbájáde èsì wọn.
Káàkiri onírúurú pẹpẹ, a ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àgbègbè ọgọ́fà. Ìbéèrè kan pàtàkì tí à ń béèrè lọ́wọ́ wọn ni : ṣe ẹ fara mọ́ ìtumọ̀ yìí? Ọ̀nà méjì ni a pín àkọsílẹ̀ àbá ìtumọ̀ wọ̀nyí sí: (1) ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ gbọ̀ngbọ̀n àti (2) àwọn kókó mìíràn tó jẹ mọ́ ìṣe, àwọn àwòmọ́ àti àbájáde ìdarí.
Àbájáde lórí ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ gbọ̀ngbọ̀n
A béèrè àwọn ìbéèrè lórí gbólóhùn kọ̀ọ̀kan àti àwọn àkíyèsí lórí wọn ní ìpín mẹ́rìndínláàdọ́rùn-ún (86%) pẹ̀lú ìdáhùn ìjọhẹn lórí ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ gbọ̀ngbọ̀n. Ẹ lè rí èsì àbájáde wa nínú àtẹ ìsàlẹ̀ yìí.
Àbájáde àwọn àmúyẹ mẹ́ta mìíràn tí a lè ní láti di ìdarí.
A tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé kíkún ìtumọ̀ ohun tí ìdarí jẹ́ nípa àkọsílẹ̀ àwọn ìṣe, àmúyẹ wọn, àti àbájáde ìdarí. Láti lè jẹ́ kí àwọn àmúyẹ ìdarí yé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àgbègbè wa yékéyéké, a béèrè èsì àbájáde lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àgbègbè lórí ìsòrí-abẹ́-ìsòrí kọ̀ọ̀kan. Ní ìpín tó dára níwọ̀nba, a rí ìpín méjìdínláàádọ́rin sí mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí wọ́n gbà pẹ̀lú ìtumọ̀ náà. Àtẹ ìsàlẹ̀ yìí ṣàfihàn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àbájáde wa.
Àbájáde àwọn àmúyẹ àkòrí.
A sọ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti béèrè ìbéèrè, láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí ó ń jẹwọ́n lọ́kàn, àti láti dábàá lórí bí a ṣe lè mú ìdàgbàsókè bá ìtumọ̀ náà. Ní abala yìí, a óò rí àwọn èsì tó gbámúṣé tí a rí gbà lọ́wọ́ wọn. Àwọn ọ̀nà márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn èsì tí a rí gbà jẹ mọ́:
- ìdí pàtàkì àti ìgbòòrò ìtumọ̀ náà
- Ipa àwọn adarí,
- ipa tí ìyàtọ̀ àṣà ń kó lórí ìdarí (àwọn ìṣe wọn),
- àwọn ẹdùn-ọkàn tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ sísọ,
- ṣíṣàlàyé yékéyéké bí a ṣe lè ṣe àmúlò ìtumọ̀ náà lọ́nà tó dára.
- Pàtàkì àti bí ìtumọ̀ náà ṣe gbòòrò sí.
A gba àwọn ìbéèrè díẹ̀ láti ṣàlàyé pàtàkì àti bí ìtumọ̀ ìdarí ṣe gbòòrò tó. A rí i pé ó ṣe pàtàkì láti ṣàlàyé yékéyéké lédè wa nípa ìtumọ̀ náà. Nítorí ìdí èyí, a ṣe àmúlò àkọsílẹ̀ tí ó ṣàlàyé pàtàkì ìtumọ̀ yìí láti lè jẹ́ atọ̀nà fún àwọn èròǹgbà wa mìíràn láti kọ́ àti láti ṣe àmúlò ètò ìdarí, bákan náà láti lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí àbá fún ẹni kọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹgbẹ́ àgbègbè wa níbikíbi tí wọ́n bá ń wá ọnà láti ṣe ìmúrólágbára ìdarí lọ́nà tiwọn.
- Ipa àwọn adarí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí àtakò àwọn ìdarí sí pínpín sí ẹ̀ka àti èmi ìpín sísọ̀rí àgbájọ ẹgbẹ́. Bí àkọsílẹ̀ lérefèé ṣe ṣàlàyé pé “ìdarí kò níṣe pẹ̀lú ipò tàbí iṣẹ́ kan pàtó,” a ṣe ìpinnu láti tẹnumọ́ kókó yìí nípa ṣíṣàlàyé tààrà nípa àwọn ìwà ẹ̀tọ́ tí àgbájọpọ̀ àjọ wa pẹ̀lú àlàyé lórí àwọn abala kan tí kò ní àlàyé tààrà lórí ipele àwọn ipò tí a ní. Fún àpẹẹrẹ, a ṣe àyípadà “Ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́”, tí ó dàbí ìlànà látòkè-wálẹ̀, pẹ̀lú “ìdásí” tí ó fi ọ̀nà sílẹ̀ fún àṣà ìpinnu alájọṣepọ̀.
Koko mìíràn fún alaye kíkún dá lórí ìbáṣepọ̀ láàárín àwọn agbára àti akitiyan ẹni kọ̀ọ̀kan àti iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe. Nínú àtúnṣe ìtumọ̀ yìí, a pinnu láti ṣe àfihàn lẹ́kùnún rẹ́rẹ́ bí akitiyan àti ìṣe ẹni kọ̀ọ̀kan ṣe jọ níṣe pọ̀ ní pẹ̀kírẹ̀kí pẹ̀lú bí a ṣe lè ní ìmọ̀ àjọṣepọ̀ àti ìpinnu àjọṣe, pàápàá jù lọ láwùjọ ẹgbẹ́ Wikimedia.
- Ipa tí ìyàtọ̀ nínú àṣà ń kó lórí àmúyẹ ìdarí
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àgbègbè mìíràn ń béèrè lẹ́kùnún rẹ́rẹ́, ipa tí àṣà ń kó nínú ìdarí, pàápàá jù lọ nínú àwọn ìṣe àti àmúyẹ àwọn adarí. A gbìyànjú láti fún wa ní ìtumọ̀ ìdarí tí ó fún wa ní òye nípa ohun tí ìdarí jẹ́, síbẹ̀, a gbà pé ìdarí máa ń “jẹ yọ lóríṣiríṣi ọ̀nà, tí ó lè jẹmọ́ èdè, àṣà àti àwùjọ tí a bá ń gbé”. Ó yé wa gbàǹgbàgbangba pé èyí lè máa ní ìtumọ̀ kan pàtó fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n a pinnu láti máa ṣe àyípadà sí ìtumọ̀ tí a fún ìdarí. Kàkà bẹ́ẹ̀, láti fèsì sí èyí àti àwọn ìbéèrè àti àwọn ẹ̀dùn ọkàn àwọn mìíràn tí kò sí nínú àkámọ́ ìtumọ̀ tí a fún ìdarí, a ṣe ìdásílẹ̀ abala awọn Ìbéèrè tí a sá sà máa ń béèrè, níbi tí a ti ṣàlàyé bí ìtumọ̀ wọ̀nyí ṣe lè yé wa yékéyéké.
- Àlàyé lórí ìlò ọ̀rọ̀
Àwọn ìlànà mìíràn lórí àkọsílẹ̀ ìtumọ̀ ni a rí gẹ́gẹ́ bí ìlànà tó gbòòrò púpọ̀ jù, tàbí tí ìtumọ̀ náà farasin tàbí ní ìtumọ̀ mìíràn tí ó yàtọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ṣíṣàpèjúwe ìdarí gẹ́gẹ́ bí ohùn tí ó ní “ìtumọ̀ púpọ̀” jẹ́ èrò tí a lè jiyàn rẹ̀: sí àwọn mìíràn, “ọ̀rọ̀ jinlẹ̀” fihàn pé ìdarí máa ń jẹyọ lọ́pọ̀ ìgbà láìsí èròǹgbà kankan lọ́kàn, lọ́nà míì ẹ̀wẹ̀ “ọ̀rọ̀ onípánna” kìí ní àlàyé kan ni pàtó, ó sìn máa ń ní ìtumọ̀ tó farasin. A ṣe àtúnṣe sí èyí nípa ṣíṣe àyọkúrò àwọn ọ̀rọ̀ onípánna àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ìtumọ̀ wọn gbòòrò bẹ́ẹ̀ kúrò lọ́nà tí ìtumọ̀ tí a fún ìdarí yóò fi yé gbogbo ènìyàn, ohun tí a ṣàlàyé gẹ́gẹ́ ni ìtumọ̀ ìdarí ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a bá ń sọ.
- Àwọn ohun gbòógì tí ó ń jẹ wá lọ́kàn lórí ṣíṣàmúlò àti àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn
A gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè àti èrò lórí bí ìtumọ̀ yìí yóò ṣe di àmúlò ni àwọn àwùjọ àgbègbè wa. A gba èrò àwọn ènìyàn lórí àwọn ìpinnu owó ìrànwọ́, ètò ìdarí tí kò ní àbòsí nínú àti ìtọpinpin àwọn adarí láti ṣe ẹ̀tọ́. A ti gbìyànjú láti dáhùn lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú abala Àwọn ìbéèrè Tí a Sáàbà Máa ń Béèrè. “Báwo ni a ṣe lè mú ìtumọ̀ jáde nínú ìtumọ̀ ohun tí ìdarí jẹ́,” tí a ti pèsè láti kà ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìtumọ̀.
Lẹ́yìn tí a ti sọ èyí, ìtumọ̀ náà ṣì dá lórí ìlànà tó gbòòrò lórí ìwà-ẹ̀tọ́ àti àwọn àmúyẹ tí a ń ṣàkíyèsí lọ́wọ́lọ́wọ́ àti àwọn tí a gbà lérò nínú àjọ-àpapò Wikimedia. Ìtumọ̀ yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ fún Ìdàgbàsókè Ìdarí Ẹgbẹ́ Àwọn Òṣìṣẹ́, bí a ṣe fò fẹ̀ẹ̀rẹ̀ sórí àkọsílẹ̀ ètò ìdàgbàsókè tí yóò ṣe àtúnṣe àwọn àpẹẹrẹ bí a ṣe lè ṣe àmúlò àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyí ní àgbègbè ẹni kọ̀ọ̀kan wa bí wọ́n ṣe yàtọ̀ sí lédè, àti àwùjọ ètò-ọ̀rọ̀-ajé àti ìṣèjọba wọn nínú àjọ-àgbájọpọ̀ wa. Ọkàn nínú àwọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ wà ninu ipele tí ó kàn ni lati ṣe àgbájọpọ̀ àwọn ìròyìn àti abá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ lórí ètò ìdarí, iṣẹ́ àti ẹ̀kọ́ wọn. Ẹ tẹ́tí léko fún àwọn ìròyìn mìíràn tí a óò tẹ̀ jáde láìpẹ́.
Can you help us translate this article?
In order for this article to reach as many people as possible we would like your help. Can you translate this article to get the message out?
Start translation