Ìforúkọsílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún Wikimania 2025

Translate this post

Wikimania ń ṣe ayẹyẹ ọdún ogún rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀dà àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, a sì fi tọkàntọkàn pè ọ́! Yálà ní ojú ara tàbí lórí ayélujára, a fẹ́ kí o dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe ìrántí ogún ọdún ti àwọn àpéjọ àgbáyé tí ó ń fún wa lókun ní ọ̀nà tí a fi ń dá ìmọ̀ sílẹ̀ tí a sì ń pín in ní ọ̀fẹ́.

Fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ láti lọ sí àpéjọ náà ní Nairobi, Ẹgbẹ́ Aṣojú Ètò náà ń ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ìforúkọsílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ṣáájú àkókò ní ọdún yìí. Ìrètí wa ni láti mú kí ètò ìrìn àjò rọrùn fún àwọn ọ̀mọ̀wé tí a gbà.

Forúkọ sílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kan láti lọ sí Wikimania 2025 ní Nairobi títí Õjọ́ Kẹjọ Oṣù Ọpẹ́ 2024.

Àlàyé nípa àpéjọ náà

A gbé e wá fún yín láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Wikimedia láti gbogbo agbègbè Ìlà Oòrùn Áfíríkà, àkòrí Wikimania 2025 yóò jẹ́ “Wikimania@20: Àkójọ. Ipa. Ìpamọ́.” èyí tí ó ń wá láti ṣe ayẹyẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì àti ipa tí ètò wa ní nígbà tí ó ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ tí yóò mú kí àwọn iṣẹ́ àkànṣe Wikimedia wà ní ìpamọ́ àti kí wọ́n kún inú ètò náà.

Àpéjọ náà yóò wáyé láti ọjọ́ kẹfà sí ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹjọ, pẹ̀lú àwọn ìgbòkègbodò tó ṣáájú àpéjọ náà tí a tún ń gbèrò láti ṣe ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹjọ. Láìpẹ́, a ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ètò náà àti ibi tí yóò ti wáyé ní pàtó.

Àlàyé nípa ìforúkọsílẹ̀

A rọ̀ ọ́ pé kí o bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí ìforúkọsílẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ rẹ ní báyìí. A ó ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìwé ìforúkọsílẹ̀ náà ní ìbámu pẹ̀lú ìkópa àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ nínú gbígbé ìgbésẹ̀ láti mú kí ìṣòkègbodò wa lágbára sí i àti ìdúróṣinṣin ìgbésẹ̀ wa –bóyá ó jẹ́ nínú ìgbòkègbodò orí ayélujára tàbí èyí tí kò sí lórí ayélujára.Jọ̀wọ́ ríi dájú pé o ṣe àpèjúwe àwọn ìlọ́wọ́sí rẹ títí sí iṣẹ́ Wikimedia, ní ìdojúkọ lórí ipa ti àwọn ìlọ́wọ́sí wọ̀nyẹn àti àtìlẹ́yìn àwọn èrò rẹ pẹ̀lú àwọn ìjápọ̀ níbití ó bá ṣeéṣe. A rọ àwọn Wikimedian láti agbègbè Ìlà Oòrùn Áfíríkà, àti àwọn Wikimedian tí wọ́n ní ẹ̀tọ́ olùṣàmúlò tí ó gbòòrò, láti fi orúkọ sílẹ̀–a nírètí pé a ó lè mú wáyé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àwọn ọgbọ́n nínú àti láàrín àwọn agbègbè nípasẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún yìí.

Àwọn ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ yọ́ọ̀ bo ìrìn àjò, ibùgbé àti ìforúkọsílẹ̀. Bíi ti àwọn ọdún tó ti kọjá, àwọn ọ̀mọ̀wé ni a ó bèèrè láti ṣe olùyọ̀ǹda ara ẹni fún wákàtí mẹ́rin sí mẹ́fà ní Wikimania, pẹ̀lú àyè láti ṣe olùyọ̀ǹda ara ẹni fún àkókò tó pọ̀ sí i bí wọ́n bá fẹ́. Gbogbo àwọn tó bá gba ẹ̀kọ́ náà ni ètò ìbánigbófò ìrìnàjò Wikimedia Foundation yóò bo.

A ó fi àbájáde ìforúkọsílẹ̀ náà tó àwọn tó forúkọ sílẹ̀ létí ní oṣù Kẹta.

Àwọn ìbéèrè?

O lè kà síi lórí Wikimania Wiki o lè kàn sí ẹgbẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìbéèrè èyíkéyìí ní wikimania-scholarships@wikimedia.org.

Karibuni Nairobi!

Wo gbólóhùn ìpamọ́ ìwádìí naa.

Can you help us translate this article?

In order for this article to reach as many people as possible we would like your help. Can you translate this article to get the message out?